27/05/2026
ÀYÁJỌ́ ÀWỌN ỌMỌDÉ/CHILDREN'S DAY
Ọmọniyì, Ọmọnidẹ, Ọmọ-ní-àsẹ̀yìndè tó bá dalẹ̀. Àwọn Yorùbá ṣe àpèjúwe àwọn ọmọ gẹ́gẹ́ bíi àjogúnbá àwùjọ torí pé ipò àkànṣe ni àwọn ọmọ wà fún ìwàláàyè àti ìlọsíwájú àwùjọ. Nítorí náà àṣà ìpìlẹ̀ yín ń fọn rere ipa gbòógì àwọn ọmọ ọmọdé àti ìdí fún ìsọ-ni-dèniyàn àti ìfinimọlé àwùjọ tó péye láti lè máa hùwà ọmọlúàbí.
A kú àyàjọ́ àwọn ọmọdé lágbàáyé
Òdòdó ẹyẹ wa kò ní rẹ̀ dànù
The Yorùbás describes children as the heritage of the society because children occupy a special place in societal survival and continuity. Children are esteemed and appreciated. Thus, the embedded culture propagates the essentiality of children, the need for proper socialisation and internalisation to make a responsible being (Ọmọlúàbí).
Happy Children's Day
📷 Pinterest
24/05/2026
IRUN ṢÍṢE/HAIR-PLAITING
Irun ṣíṣe jẹ́ ohun àrà ọ̀tọ̀ lágbàáyé tí pàtàkì sì rẹ̀ sí gùnmọ́ sítáì, ìṣètọ̀jú àti ìdàgbàsókè àwùjọ ajẹmáṣà. Irun ṣíṣe jẹ́ ìdánimọ́ tí ó lọ́ọ̀rìn fún ẹwà, ìṣelọ́ọ̀ṣọ́.àti ipò àwùjọ láàárín àwọn Yorùbá. Ní àwùjọ Yorùbá, a ní àwọn òrìṣà tí wọ́n jẹ mọ́ iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan. Ọ̀ṣun tí ó jẹ́ òrìṣà tí a somọ́ irun ṣíṣe ni òrìṣà omi, abiyamọ, ìfẹ́, àlàáfíà, ìlọsíwájú àti ẹwà. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ìwáṣẹ̀ Yorùbá, Ọ̀sun ni onídìrí àkọ́kọ́ nínú àwọn òrìṣà.
Hairdressing and hairstyles are global phenomena that achieve the purpose of styling, grooming, and socio-cultural development. Aesthetics, adornment, social status, and identification are strong features among the Yorubas. In Yorubaland, there is an òrìṣà associated with every profession. Ọ̀ṣun , the Yoruba òrìṣà , associated with hairdressing, is the goddess of fresh waters, fertility, love, peace, prosperity and beauty. According to Yoruba myths, Osun was the first deity/goddess to use a comb, and she was also the first hairdresser.
©Oriire
21/05/2026
ÈDÈ ÌPERÍ YORÙBÁ /YORÙBÁ LEXICON
Kòkòrò ìwúkàrà:àrùn ọ̀súnwúúrú tí a n rí
lẹ́nu, ara, inú àti oju araobìnrin ṣùgbọ́n tí ó lè di àrùn gidi lára àwọn tí àjẹsára wọn ti gbàbọ̀dè.
Candida Yeast-like fungi commonly found in
the normal flora of the mouth, skin, intestinal tract and va**na, but can become clinically infectious in immune compromised people.
19/05/2026
ỌDÚN AGẸMỌ/AGẸMỌ FESTIVAL
Ọdún Agẹmọ jẹ́ ọdún pàtàkì tí ó máa ń wáyé ní ìlú Ìjẹ̀bú, ó sì jẹ ayẹyẹ tí ó so okùn ìṣọ̀kan àwọn aráàlú jákèjádò orílẹ̀ àgbáyé. Àwọn ọmọ ìlú àti aráàlú Ìjẹ̀bú gbàgbọ́ pé ọdún náà máa ṣínà ìbùkún, ó ń tọwọ́ àlá àgàn bosùn, ìlọsíwájú ìlú, àti ìdábòòbò. Èẹwọ̀ ni fún àwọn obìnrin láti ní ìbáṣepọ̀ tààrà pẹ̀lú Agẹmọ. Lára àwọn tí ó máa ń wáyé ní ìkópa àwọn eégún, ijó, ìlú, ìwúre, ètùtù àti ìṣàfihàn ajẹmáṣà tí ó wuyì, gbogbo èyí wà fún ìsọlọ́jọ àwọn ohun ọ̀wọ̀ àti òfìn ajẹ́mẹ́ẹ̀mí Yorùbá bákan náà ló ń mú kí ẹ̀kà ìrìnàjò-afẹ́ àti ọrọ̀ ajé ìbílẹ̀ gbòòrò si. Ọdún Agẹmọ yóò bẹ̀rẹ̀ ni pẹrẹu lónìí.
The Agẹmọ Festival stands as one of the most sacred and unifying celebrations in Ìjẹ̀bú land, a timeless tradition that binds sons and daughters of the soil across generations and continents. The Ìjẹ̀bú people believe the festival brings divine blessings, including fertility for barren women, communal prosperity, and ancestral protection. Women show deep reverence by observing taboos such as avoiding direct contact with the Agẹmọ.
The festival is alive with masquerade performances, ijó drumming, prayers, sacrifice, and vibrant cultural displays, all of which preserve the Yoruba spiritual ethos while also boosting local tourism and economy. The festival kicks off today.
17/05/2026
ÀWỌN ÀṢÀYÀN ÈDÈ ÀMÚLÒ LÍTÍRÉṢỌ̀ YORÙBÁ /YORÙBÁ LITERARY TERMINOLOGIES
Èyí ni díẹ̀ nínú àwọn àṣàyàn èdè Ìperí nínú lítíréṣọ̀ Yorùbá
These are some selected terminologies used in Yoruba literary studies.
Lítíréṣọ̀ alohùn Yorùbá - Yorùbá Oral Literature
Lítíréṣọ̀ àpilẹ̀kọ Yorùbá - Yorùbá Written Literature
Ewì alohùn: Oral poetry
Ewì àpilẹ̀kọ: Written poetry
Eré oníṣe/Onítàn: Drama
Ìtàn àròsọ: Prose
Kókó ọ̀rọ̀: Theme
Ìlò èdè: Diction
Ìṣọwọ́kọ̀wé: Stylistics
Àhunpọ̀ ìtàn: Plot
Ibùdó ìtàn: Setting
Ẹ̀dá ìtàn:Character
Ìfìwàwẹ̀dá: Characterization
Ọ̀gbọ́n ìsọ̀tàn:Narrative technique
Lámèyító: Criticism
Àlọ́ àpagbè: Folktale
Àlọ́ àpamọ̀: Riddle
14/05/2026
Ṣẹ̀pẹ̀tẹ̀rí ni ìlú tí ó tóbi jù ní ìjọba ìbílẹ̀ Ṣakí East ní Òkè -Ògùn, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Orúkọ oyè ọba ìlú náà ni Ọbalùfọ̀n. Elédùà jíìkí ìlú Ṣẹ̀pẹ̀tẹ̀rí pẹ̀lú àwọn nǹkan àlùmọ́nì bíi táńtáláìtì, kaolínì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni iṣẹ́ abínibí tí ó gbòòrò jùlọ ní ìlú náà. Wọ́n ni àwọn ibùdó ìṣẹ̀mbáyé àti ìrìnàjò afẹ́ bíi Old Ọ̀yọ́ National Park, Ìgbàlẹ̀ Yemọja àti àwọn ibùdó ìwakùsà àtijọ.
Ṣẹ̀pẹ̀tẹ̀rí is the biggest town in the Saki East Local Government Area of Oke-Ogun, Oyo State. Ṣẹ̀pẹ̀tẹ̀rí is a town blessed with mineral resources such as tantalite, columbite, cassiterite, kaolin, and granite. Agriculture is the prominent craft of the people of Ṣẹ̀pẹ̀tẹ̀rí. The town has tourism potential such as, Old Ọ̀yọ́ National Park, Iyemoja Shrine and Old mining sites.
12/05/2026
🥁 ÒGÌDÌGBÓ & ÀGÍDÌGBO 🪕
Lówe lówe là á lu ìlù Ògìdìgbó, ọlọ́gbọ́n níí jo, ọ̀mọ̀ràn níí mọ̀ Ọ́. Orísìí ìlù kan ni ìlù Ògìdìgbó, bákan náà orísìí ìlù kan ni ìlù Àgídìgbo.
Ìwádìí fi hàn pé ìlù Ògìdìgbó kìí ṣe ìlù gbogbogbòò, Aláàfin nìkan ló máa ń jo, fún ìdí èyí, a lè pè ní ìlù awo tàbí ìlù àrokò àwọn Amòye. Ìlù Àgídìgbo kìí ṣe ìlù tààrà, a lè pè ní gìtá tàbí dùrù àbáláyé torí pé, wọn to irin sí lára àwọn irin náà ló máa mú ohun jáde.
The Ògìdìgbó drum speaks in proverbs; only the wise can dance to it, and only the discerning understand it. The Ògìdìgbó drum is a unique drum, just as the Àgídìgbo is its own distinct instrument. Research shows that the Ògìdìgbó drum is not a common drum; it is danced to only by the Aláàfin. For this reason, it may be called a sacred drum or a coded drum of the sages. The Àgídìgbo cannot be fully classified as a drum; it may be described as an ancient guitar (dùrù àbáláyé) because iron pieces are attached to it, and it is from these metal parts that its sound emerges. 🎶🪓
10/05/2026
ÌJÍRÒRÒ LÓRÍ LÍLÒ ÀPÈLÉ ORÚKỌ ỌKỌ LẸ́YÌN ÌGBÉYÀWÓ/DISCUSSION ON USAGE OF HUSBAND'S SURNAME AFTER MARRIAGE
Ọ̀mọ̀wé Adébáyọ́wà Álímì-Adéníran wí pé:
Àṣà ọ̀làjú ló bí kí àwọn òbìnrin ìwòyí ó máa jẹ́ orúkọ ìdílé ọkọ wọn. Àṣà náà sì dára torí pé ó pààlà láàrin abílékọ àti omidan. Àwọn aṣabìnrin tí wọn gùnlé ìṣègbèfábo àti àwọn ọkùnrin akúrẹ̀tẹ̀ amúwàjobìnrin ni wọn faramọ́ kí ìyàwó ó máa jórúkọ ìdílé bàbá ẹ̀ nílé ọkọ. Àwọn obìnrin tí ìgbéyàwó wọn daagun fún ìdí kan tàbí òmíì pẹ̀lú àwọn obìnrin atirobẹ́lẹ́ṣindọ́gba tí wọn kò fẹ́ wà lábẹ́ àṣẹ ọkọ ni wọn kì í fẹ́ jẹ́ orúkọ ìdílé ọkọ wọn. Ìwádìí fi ìdí ẹ̀ mùlẹ̀ pé àwọn obínrin alágbára kan tí wọn ya aṣa tí wọn jẹ́ ọlọ́kọ púpọ̀ (polyhandrists) ni kì í fẹ́ jẹ́ orúkọ ìdílé ọkọ wọn ní àwùjọ Yorùbá. Tí àwọn òbí ìyàwó bá ti fa àgbò ọmọbìrin wọn fún eégún ìdílé ọkọ, ẹ̀tọ́ ni kí wọ́n ó fi okùn rẹ̀ sílẹ̀.
It is modern civilization that introduced the practice of women bearing their husbands’ family names. The custom is a good one because it draws a distinction between a married woman and a maiden. It is radical feminists who supports the idea that a wife should continue bearing her father’s family name in her husband’s home. Women whose marriages have turned sour for one reason or another, along with extremist advocates of women’s liberation who do not want to live under a husband’s authority, are usually the ones unwilling to bear their husbands’ family names. Research has established that some powerful women who reject the tradition are women with multiple husbands (polyhandrists) in Yorùbá society. Once the bride’s parents have handed their daughter over to the ancestral lineage of her husband’s family, it is only right that they completely release their hold on her.
© Dr. Adébáyọ́wà Álímì-Adéníran
08/05/2026
Ó ṣé pàtàkì láti ṣe àwọn nǹkan àti ibùdó ìṣẹ̀mbáyé ajẹmọ́tàn lọ́jọ́ kí a rántí kí a sì lè kẹ́kọ̀ọ́, bákan náà ni yóò jẹ́ kí a lè ọlá, iyì oun ẹyẹ fún àwọn tí ìtàn tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ náà rọ̀mọ́. Tí a ba se nǹkan ìṣẹ̀mbáyé lọ́jọ̀ láì fi igbá kan bọ̀kan nínú lórí ipò tí ó wà, òtítọ́ irú ìtàn bẹ́ẹ̀ kò ní parẹ́ láéláé.
It is important to preserve artefacts and heritage sites from historical events so we can remember, learn about and honor those who were involved. When an artifact is conserved to retain its current condition, it preserves the truth of the historical story for generations to come.
07/05/2026
Yorùbá Public Library yóò ṣètò àti ní àǹfààní sí ìmọ̀ ajẹmáṣà Yorùbá káríayé nípa pípagi dínà ìpèníjà àì-ráyé dé àgbègbè àti àìlè-fojúrí.
Yorùbá Public Library will provide global access to Yorùbá Cultural knowledge, breaking geographical and physical barriers.