03/11/2022
MÁJẸ̀MÚ MI SÍ Ẹ̀YIN ÈNÌYÀN MI NÍ ẸKÙN ÌDÌBÒ KÁJỌLÀ ÀTI ÌLÚ Ọ̀YỌ́ LÁPAPỌ̀( OGA).
Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ:
Ẹ̀yin ènìyàn mi àtàtà, láìsí tàbí ṣùgbọ́n, láìfi epo bọyọ̀, ìlú Ọ̀yọ́ àti agbegbe rẹ̀ tí ayé ti mọ̀ lọ́jọ́ tí ó ti pẹ́ ń kojú àwọn ìpèníjà tí ó ń mú ìdàrúdàpọ̀ wá. "Bí oko kò bá jìn ilá kìí kó", fún ìlú láti gba òmìnira kúrò lọ́wọ́ ìpòrurù, ìdààmú, àìlọ síwájú, àti àwọn ohun tí o le máa fa ọwọ́ agogo ìlú sẹ́yìn, ìfojúsùn, ọgbọ́n àtinúdá, ìrònú àti ìròrí jinlẹ̀ nìkan ni ó le mú ìlú gbé oúnjẹ fẹ́gbẹ́ gbàwo bọ̀. Àyípadà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni yóò sì bá irúfẹ́ ìlú bẹ́ẹ̀. "Ká kó ilà kúrọ̀ lẹ́kọ ẹ̀kọ ò kúkú kọlà", kí dáadáa tún leè sùnwábọ̀, èwe ìwòyí kò gbọ́dọ̀ sọ pé ẹnu àgbà ń rùn( ìbà àgbà).
Àwọn baba wá oníròrí tó dọ́ṣọ̀ Wọ́n wí pé "Òrìṣà tí a bá ń kóbì bọ fún àìmọye ọdún tí kò gbeni, bí a bá pa irúfẹ́ òrìṣà bẹ́ẹ̀ tì kò burú rárá ", ó dífá fún ìwà àìlófin, àìníjàánu, afọ́jú ń fafọ́jú lọ́pàá, arọ ń pọn arọ sẹ́yìn èyí tí àwọn kan ti gùnlé ti Wọ́n sì sọ di agbádá láti iye ọdún yí wá. Ṣé dandan ni ká tún máa ṣe ìrìnàjò tí kò ní ibìkan pàtó tí à ń rè bí?, àbí a ti ṣe tán láti wọ ẹ̀wù àwọ̀lékè káyé jẹ àgbọ̀nrín èṣín lọ́bẹ̀?. Bí a kò bá torí iṣu jepo, ó mà yẹ ká torí epo jẹṣu, ọjọ́ iwájú, ẹ̀yìn ọ̀la àwọn ọmọ wa ló jàjù, ká fọwọ́ ara wa tún wà ara wa ṣe, ṣe bí "ẹnu ẹni la fí kọ méèjẹ".
Ẹ̀yin ará mi tòótọ́, àwa tí a ní èrò ń gbà tó yè kooroko fún ìfojúsọ́nà ọjọ́ ọ̀la tí kò ní mẹ́ẹ́rí, olùdìbò nìkan ṣoṣo kọ́ la jẹ́, bí kò ṣe alábòójútó fún irúfẹ́ aṣojú-ṣòfin tí a fẹ́ nípò, ṣùgbọ́n kí ni ìpèsè wa fún ọjọ́ ọ̀la tí à ń sọ ní pàtó?, nítorí kí àwùjọ le gòkè àgbà, kìí ṣe ọ̀rọ̀ àbámọdá lásán, ọ̀rọ̀ orí ahọ́n kọ́.
Mo gbèrò láti tẹ́ pẹpẹ ìríjú, àfojúsùn, àlá rere tí kò lóǹkà, àdìsọ́kàn mi láti dúró ṣinṣin àti pípè ìlànà òfin èyí tí yóò yọwá kúrò nínú ọ̀fìn ìfàsẹ́yìn, àìbẹ́gbẹ́pé, lílànà ọjọ́ iwájú tó peregedé fi gbọ̀ọ̀rọ̀ jẹkà fún àwọn ènìyàn ti kò rọ́wọ́ họrí, ẹ̀yìn wá ọ̀la tó fa kíki fún àwọn èwe tó ń bọ̀ lọ́nà, lílo ìlànà ọgbọ́n àtinúdá, pẹ̀lú ọ̀làjú fún kíkẹ́sẹ járí láti di ògúnná gbòǹgbò ní ìlú kóówá wa, gbígbé ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin ìlú sí oókan àyà, ìtọ́jú àwọn arúgbó, wíwúlò fún àwọn ọ̀dọ́, ní pàtàkì jù lọ àwọn abarapá kún mi lójú jọjọ.
"ÌFOJÚSÙN MI"
Ṣí ẹ̀yin olólùfẹ́ mi, ẹ̀yin rere tí ìlọsíwájú ẹkùn ìdìbò KÁJỌLÀ jẹ́ túláàsì lóókan àyà yín, àti gbogbo àwa olùgbé ìlú Ọ̀yọ́ lápapọ̀. Mo ṣe tàn láti fara mi jìn, fún sínsin ìlú àti ẹ̀yin ènìyàn mi, láti ṣiṣẹ́-jà fún àwọn ẹ̀tọ́ tó lóòrìn fún ìgbáyégbádùn ìrọ̀rùn ẹ̀yin ènìyàn mi lápapọ̀, fífi ìròrí kún ìròrí, fífi ikùnlukùn pẹ̀lú àwọn àgbà ẹgbẹ́, onílàákàyè olóṣèlú, àwọn amòfin-ṣòfin, àti àwọn obìnrin àtàtà nílùú láti dìjọ forí okòó sọ̀ọ́dún lórí àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì bíi " àwọn ẹ̀tọ́ ará ìlú, ìgbáyégbádùn ìrọ̀rùn, ètò ọrọ̀ ajé, ààbò ẹ̀mí àti dúkìá, àyíká tó ṣeé gbé, ìmójútó ètò ẹ̀kọ́, ní pàtàkì jù lọ gbígbòòrò àti ìgbéga ìlú Ọ̀yọ́ lápapọ̀. Ẹ gbà mí gbọ́ pé kí àlá yìí le wá sí ìmúṣẹ ló jẹmi lógún.
" ÈRÒŃGBÀ MI"
Ènìyàn tó bá mojú Ògún, ẹ jẹ́ kó pabì nírè, bẹ́ẹ̀ " Ajá ìwòyí ló mọ ehoro ìwòyí lé". Ènìyàn tí ó bá tọ́ tí ó sì yẹ, òhun ló yẹ ká fi ìbò wa gbé dórí ipò adarí láti jẹ́ kí gbígbòòrò àti gbígbádùn ràwọn ènìyàn mu omi lóókan àyà rẹ̀, ti yóò sì ríi gẹ́gẹ́ bí ìdí pàtàkì tí a fi yàn án sípò. Èmi Olúgbénga George Ọlátúnjì(Ọ̀GÁ), ń ṣe ìlérí pé bí ẹ bá gbà mí láàyè láti di aṣojú yín tó ṣeé fọkàn tán fún ẹ̀yin ènìyàn rere ẹkùn ìdìbò KÁJỌLÀ ní ìlú Ọ̀yọ́ àti àgbègbè rẹ̀. Mò ń fi ìgbà àti wákàtí yìí ṣèlérí láti fi tọkàntọkàn jìn, gbogbo ipá mi, àkókò mi, ìrírí mi nínú òṣèlú, àti àwọn ìrírí mi lọ́kàn ò jọ̀kan nígbà tí mo fi ṣe aṣojú tó lààmì-laaka fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nígbà tí mo wà nílè ẹ̀kọ́ yunifásítì, ìlà kàkà mi nípa òṣèlú, òye mi lórí ẹ̀kọ́, ìmọ̀ mi nípa ọrọ̀ ajé, kíkó ara ẹnì níjàánu àti èrò láti sin àwọn ènìyàn ìlú tọkàntọkàn láìní ìyọlẹ́nu, pẹ̀lú níní àkóyawọ́, kí àbá mi tó lóòrìn wá sí ìmúṣẹ pẹ̀lú ìfọwọ́sọwọ́pọ̀ ẹ̀yin ènìyàn mi.
ÌLAPA ÈRÒ RERE "Ọ̀GÁ" LÓRÍ ÌSÈJỌBA TÒÓTỌ́.
Àwọn bàbá wa ọ̀jọ̀gbọ́n wí pé "bí ẹyẹ bá ṣe fò ni a ṣe ń ju òkò o rẹ̀". Ṣíṣe ìjọba àjàǹbàkù, ìjọba ta ń kú ta ń kù? ti ré kọjá lọ, èyí tí kò fún àwọn ará ìlú ní oore ọ̀fẹ́ láti fojú rinjú pẹ̀lú àwọn aṣòfin wọn lẹ́yìn ìpolongo ètò ìdìbò, àrékọjá ti bá àná, ìgbà ọ̀tun ti yóò sànwá bọ̀ ti dé, ètò ìṣèjọba mi yóò fàyè sílẹ̀ láti má a fikùn lukùn lórí èrò àwọn ará ìlú àti wíwá ojúlówó ojútùú sí ohun gbogbo tí ó bá ń rú wọn lójú.
ÌLAPA ÈRÒ RERE "Ọ̀GÁ" FÚN ÀWỌN OBÌNRIN.
Àwọn iyọ̀ ayé, ó débẹ̀ ó dẹ̀rọ̀ ṣe pàtàkì fún ìlọsíwájú àti ìgbé lárugẹ ìlú. Fífún àwọn obìnrin rere láàyè tó gbọn gbọ́n àti ṣíṣe àtìlẹ́yìn lórí àwọn èrò ọkàn wọn tó ṣeyebíye àti gbígbòòrò ipa pàtàki yóò ma kó nílùú, pípèsè ètò ìlera, lílé ìṣẹ́ àti òṣì dànù, gbígbé lárugẹ àṣà mímọ rìrì àwọn obìnrin láwùjọ, ìpèsè iranlọwọ fún àwọn opó àti àwọn ti Wọ́n ní ìpèníjà ara.
ÌLAPA ÈRÒ RERE 'Ọ̀GÁ' FÚN ÀWỌN Ọ̀DỌ́.
"BÍ òròmọ adìẹ kò bá kú ní rèwerère ó di dandan kó jẹ́ àjẹtẹ́rùn àgbàdo", bẹ́ẹ̀, ọmọdé òní ni yóò dàgbà bó dọ̀la, òrìṣà tí a bá ń sìn tí à ń lé àwọn ọmọdé kúrò nídìí rẹ̀, irúfẹ́ bẹ́ẹ̀ kò ní pẹ́ parun. Ìlapa èrò, àbá dídá, àti ṣíṣe iṣẹ́ tọ àwọn ohun tó lè máa jẹ́ àfínnúfíndọ̀ṣe ní tìbú-tòrò ẹkùn ìdìbò KÁJỌLÀ àti Ọ̀yọ́ lápapọ̀, pàápàá jù lọ, ṣíṣe ètò ìrànwọ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti ní àfojúsùn fún ògo orílè èdè Nàìjíríà. Fífi àyè sílè fún àwọn ọ̀dọ́ láti jẹ́ kí ẹnu Wọ́n tọ́rọ̀ láwùjọ wa yálà nípa òṣèlú, ríró àwọn ọ̀dọ́ lágbára láti jẹ́ kí wọn ó leè di ipò pàtàkì mú láwùjọ wa fún ọjọ́ iwájú tó lákaakì.
ÌLAPA ÈRÒ RERE 'Ọ̀GÁ' FÚN ÀWỌN ABARAPÁ.
Ẹnikẹ́ni tí ìwọ bá nípá láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún, òhun gan-an ni ẹnìkejì rẹ tọ́jú rẹ̀. Ìlànà àparò kan ò ga jù kan lọ ti wà fún àwọn abarapá ènìyàn láwùjọ wá, mo ma sa gbogbo ipá àti agbára mi láti ri dájú pé àwọn ènìyàn ti Wọ́n ní ìpèníjà ara kò gbẹ́yìn nípa jíjẹ mùdùn múdùn ìjọba àwa araawa, àǹfààní ní ilé ẹ̀kọ́, níbi iṣẹ́, àti níbi ẹni kọ̀ọ̀kan wọn, a kò ní yàn Wọ́n ní ìpọ̀nsìn, Èdùmàrè ló kúkú fi Wọ́n dára ire fún aráyé. Ìlérí Ọlọ́run nínú ayé wọn yóò di mímú ṣe.
ÌLAPA ÈRÒ RERE 'Ọ̀GÁ' FÚN ÀWỌN ÀGBÀLAGBÀ
" BÍ ọmọdé bá láṣọ bí àgbà, kò leè lákìísà bí àgbà". Bẹ́ẹ̀, ọmọdé tó bá sọ pé tàgbàlagbà báwo?,ọgbọ́n, òye, àti àròjinlẹ̀ ayé ọjọ́ sí ni kò ní sí fún un. Pípèsè ètò ìrànlọ́wọ́ fún àwọn àgbàlagbà, láìfi ẹ̀yà, ìlú àti ẹgbẹ́ òsèlú kankan ṣe jẹ ìṣàkóso yìí lógún jọjọ.
Àwọn àgbàlagbà yóò jẹ mùkúndùn òṣèlú nípa "ìmójútó ìlera àwọn àgbàlagbà, ṣíṣe iranlowo owó fún wo láti máa dá bí ẹdun rọ̀ bí òwè níbi isẹ́ ọwọ́ kálùkù wọn. Ìgbáyégbádùn ìrọ̀rùn, láti ri dájú pé àwọn àgbà kò dàgbà ní tara lásán nítorí àárẹ̀ àbí nítorí àìrí ìtọ́jú tó péye, bí kò ṣe ki wọn dàgbà pẹ̀lú àlàáfíà ara tí kò níí ṣe pẹ̀lú ṣìbáṣìbo ẹ̀mí.
ÌLAPA ÈRÒ RERE 'Ọ̀GÁ' FÚN ÀWỌN ÌLÚ KÉKERÉ ÀTI ÀWỌN ABÚLÉ KÉRÉJE KÉRÉJE.
" Ìbí ò kú jù í, bí a ti bí ẹrú bẹ́ẹ̀ gan la bí ọmọ ". Mímú àǹfààní ìṣèjọba dé tìbú-tòrò àwọn ìgbèríko yàtọ̀ sí àwọn ará ìgboro. Ìmúratán láti kún kíkọ́ ẹ̀kọ́ ìgbàlódé rọrùn fún àwọn ará abúlé náà, pípèsè ìrànwọ́ ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti Wọ́n bá yanran tí láti tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ wọn dé yunifásítì, wíwá ojútùú sí àìní olùkọ́ tó ní àwọn ilé ẹ̀kọ́, ìpèsè ilé ìwòsàn fún àwọn ará abúlé.
Bákan náà, ìgbé lárugẹ ètò ọ̀gbìn àti ọ̀sìn àwọn ẹranko fún àwọn àgbẹ̀, nítorí pé iṣẹ́ àgbẹ̀ ni ọ̀pákùtẹ̀lẹ̀ ọrọ̀ ajé orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Dídá àwọn ará ìlú kéréje lóko òwò kéékèèké èyí tí àwọn kan ti fẹnu yaran sọ́bẹ̀ nígbà kan fún rí, ṣùgbọ́n ti wọ̀n kò mú ìlérí wọn ṣẹ. Mímú ètò òṣèlú àwa araawa dé tìbú-tòrò àwọn ti wọn kò gbé àárín ìgboro jẹ́ dandan gbọ̀n.
ÀGBÁLỌGBÁBỌ̀
Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ kò kún agbọ̀n, afẹ́fẹ́ ló ń mú wá. Àti pé " purọ́ nìyí ẹ̀tẹ̀ ló ń mú wá", gbogbo àwọn ìdí pàtàkì àti àfojúsùn tí wọ́n jẹni lógún jọjọ, èyí tí a piyamọ sókè wọ̀nyí ni wọn kò níí ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìfẹ́ inú, àbí ìlara àwọn olóṣèlú kankan, bí kò ṣe pé ìrírí mi nípa òṣèlú, ìfarasìn àti ìfarajìn mi láti sin ẹ̀yin ènìyàn mi ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ló mú mi lọ́kàn.
Mo nígbà gbọ́ pé, ojúṣe mi ni láti fi gbogbo ara ṣiṣẹ́ fún ìlọsíwájú àti ìdàgbàsókè orílẹ̀ èdè yìí ní pàtàkì jù lọ ìlú Ọ̀yọ́ lápapọ̀, èyí tí yóò jẹ́ kí ètò òṣèlú rẹ́sẹ̀ walẹ̀.
Pípakítí mọ́ra láti ri dájú pé ètò òṣèlú tí àwọn a síwájú wa jìyà fún kò mẹ́ẹ́rí lásìkò tiwa, iwájú iwájú lọ̀pá ẹ̀bìtì yóò máa ré sí. "Ẹyọ ẹnìkan kìí jẹ́ àwa dé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló ń jẹ́ èrò". Láti rí ìtàn rere kọ nípa ọjọ́ ọ̀la ní ìlú Ọ̀yọ́, igi kan èmi Olúgbénga George Ọlátúnjí(Ọ̀GÁ), kò leè dá igbó ṣe, ìfọwọ́sọwọ́pọ̀, ìgbárùkù tì, àti ìdúró tini ṣinṣin yín (ẹ̀yin ará ìlú KÁJỌLÀ), láti ríi pé àlá iyebíye fún ìran-ìran yìí wá sí ìmúṣẹ. Mi ò leè daṣe, ká dìjọ fọwọ́ wẹ ọwọ́ kí àlá wa èyí tó lóore wúrà àti fàdákà lọ le mú ìlú wa gòkè àgbà.
Bí a bá le wà ní ìṣọ̀kan, òkè téńté ni ìlú wa yóò wà, nítorí, ọmọ ẹyọ ìgbálẹ̀ kan ṣoṣo rọrùn láti kán sí méjì, ṣùgbọ́n, òṣùṣù ọwọ̀ kò ṣe é kán sí wẹ́wẹ́, Hun! "Àjòjì ọwọ́ kan kò gbẹ́rù dórí, àgbájọ ọwọ́ la fí ń sọ̀yà".
Àsìkò rè é láti tì mí lẹ́yìn, láti lo gbogbo ìmọ̀, ìwádìí, àti ìrírí mi láti jà fún ẹ̀tọ́ ẹ̀yin ènìyàn àtàtà kúrò lọ́wọ́ àwọn arẹ́nijẹ̀, Wọ́n á tún fi han ni pé kí la fẹ́ ṣe, ó tó gẹ́, alubàtá kìí dárin.
Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé" ìgbìnyànjú òní, oore ọjọ́ ọ̀la ni, ìrọ́jú àti ìfaradà ọjọ́ òní ni yóò so èso rere fún ọjọ́ iwájú tó gbọn gbọ́n, ohun gbogbo tí a bá ṣe lónìí, ọ̀rọ̀ ìtàn ni bó dọ̀la, bẹ́ẹ̀ ẹ̀yìn wá ọ̀la máà ń dùn fún àwọn ti Wọ́n ní ìrankàn dáadáa láìsí gbọ́ ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ àwọn olubi ẹ̀dá kankan, kí a má ṣe jẹ èbù lọ́dún yìí nítorí pé èbù niṣu tuntun míràn bí ó bá di àmọ́dún".
Gbígbé ìlú mi àtàtà Ọ̀yọ́ lárugẹ ló jẹ́ pàápàá ni oókan àyà mi. Níbi tí àwọn òbí mi àtàtà, àwọn akọni máni gbàgbé ti wọ́n kó ipa takuntakun fún gbígbòòrò ìlú Ọ̀yọ́, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀yin ènìyàn pàtàkì tí kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn. Ìjàrá mọ́ṣẹ́, àti ìfarasìn èyí tí yóò mú ìrọ̀rùn bá àwọn ìran tó ń bọ̀ lẹ́yìn wá ọ̀la.
Ìgbà ara gan-an làá búra, ẹnìkan kìí bù ṣàngó lẹ́ẹ̀rùn, àsìkò wa ti tó, láti sọ ètò òṣèlú alágbádá dọ̀tun, ṣíṣe àtúntò sí àwọn igun tó mẹ́hẹ, mímú ìlérí adùn ọjọ́ iwájú tí àwọn èèyàn kan ti jìyà fún wá sí ìmúṣẹ, fún àǹfààní àwọn èwe ògo wẹ́wẹ́, ki wọ́n leè kọrin rere kìwá.
Gẹ́gẹ́ bí igba ẹkẹ́ ṣe fọwọ́ tilé tí kò fi wó, igi kan kò leè dágbó ṣe. Ìfọwọ́sọwọ́pọ̀ ẹ̀yin olólùfẹ́ mi jẹ́ ohun tí owó kò lee rà, ẹ má ṣe gbàgbé pé " bí a bá tará ilé ẹni lọ́pọ̀ kò leè rà a lọ́wọ̀n -ọ́n". Kí á má ṣe ta ògo ọ̀la ìlú wa fún àwọn "Ọlọ́kùnrùn ẹ̀dá tí ma ń fi isó dúpẹ́ oore".
Èmi ni tiyín tòótọ́, ọkùnrin náà tó fẹ́ ṣiṣẹ́ ìríjú ilẹ̀ baba rẹ̀, ọmọ-ọmọ yín, ọmọ yín, àbúrò yín, olólùfẹ́ to lórí tẹlẹ́mù, ọmọlúwàbí, a ìwà pẹ̀lẹ́, aláàánú mẹ̀kúnnù, olùfẹ́ àlàáfíà. Olúgbénga George Adétúnjí, ẹ̀yin tí ẹ bí mi ni ẹ ń pèé ní "Ọ̀GÁ", ìlérí Olúwa yóò ṣẹ.